Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 12:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà tí Abramu wọ Ijipti, àwọn ará Ijipti rí i pé arẹwà obinrin ni aya rẹ̀.

15. Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Farao rí i, wọ́n pọ́n ọn lójú Farao, wọ́n sì mú un wá sí ààfin rẹ̀.

16. Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí.

17. Ṣugbọn OLUWA fi àrùn burúkú bá Farao ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jà nítorí Sarai, aya Abramu.

18. Farao bá pe Abramu, ó bi í pé, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí sí mi? Èéṣe tí o kò fi sọ fún mi pé iyawo rẹ ni Sarai?

19. Èéṣe tí o fi sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni yín, tí o jẹ́ kí n fi ṣe aya? Iyawo rẹ nìyí, gba nǹkan rẹ, kí o sì máa lọ.”

20. Farao bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì rí i pé Abramu jáde kúrò nílùú, ati òun ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 12