Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 12:10-20 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ní àkókò kan, ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ Kenaani. Ìyàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Abramu níláti kó lọ sí Ijipti, láti máa gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

11. Nígbà tí ó ń wo Ijipti lókèèrè, ó sọ fún Sarai aya rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ náà mọ̀ pé arẹwà obinrin ni ọ́,

12. ati pé bí àwọn ará Ijipti bá ti fi ojú kàn ọ́, wọn yóo wí pé, ‘Iyawo rẹ̀ nìyí’, wọn yóo pa mí, wọn yóo sì dá ọ sí.

13. Wò ó, wí fún wọn pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wá, kí wọ́n lè ṣe mí dáradára, kí wọ́n má baà tìtorí rẹ pa mí.”

14. Nígbà tí Abramu wọ Ijipti, àwọn ará Ijipti rí i pé arẹwà obinrin ni aya rẹ̀.

15. Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Farao rí i, wọ́n pọ́n ọn lójú Farao, wọ́n sì mú un wá sí ààfin rẹ̀.

16. Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí.

17. Ṣugbọn OLUWA fi àrùn burúkú bá Farao ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jà nítorí Sarai, aya Abramu.

18. Farao bá pe Abramu, ó bi í pé, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí sí mi? Èéṣe tí o kò fi sọ fún mi pé iyawo rẹ ni Sarai?

19. Èéṣe tí o fi sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni yín, tí o jẹ́ kí n fi ṣe aya? Iyawo rẹ nìyí, gba nǹkan rẹ, kí o sì máa lọ.”

20. Farao bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì rí i pé Abramu jáde kúrò nílùú, ati òun ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 12