Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 11:21-29 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

22. Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.

23. Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

24. Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra.

25. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

26. Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani.

27. Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti.

28. Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí.

29. Abramu ati Nahori ní iyawo, Sarai ni orúkọ iyawo Abramu, orúkọ iyawo ti Nahori sì ni Milika, ọmọbinrin Harani. Harani ni baba Milika ati Isika.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 11