Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 10:1-21 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìran Noa nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Lẹ́yìn ìkún omi, àwọn mẹtẹẹta bí ọmọ tiwọn.

2. Àwọn ọmọ Jafẹti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi.

3. Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣikenasi, Rifati, ati Togama.

4. Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣai, Taṣiṣi, Kitimu ati Dodanimu.

5. Àwọn ni baba ńlá àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ati àwọn erékùṣù, tí wọ́n tàn káàkiri. Àwọn ọmọ Jafẹti nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.

6. Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani.

7. Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba ati Dedani.

8. Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé.

9. Pẹlu àtìlẹ́yìn OLUWA, Nimrodu di ògbójú ọdẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ súre fún eniyan pé, “Kí OLUWA sọ ọ́ di ògbójú ọdẹ bíi Nimrodu.”

10. Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni.

11. Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Asiria, ó sì tẹ Ninefe dó, ati Rehoboti Iri, ati Kala,

12. ati ìlú ńlá tí wọn ń pè ní Reseni tí ó wà láàrin Ninefe ati Kala.

13. Ijipti ni ó bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Nafutuhimu,

14. Patirusimu, Kasiluhimu, (lọ́dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistia ti ṣẹ̀) ati Kafitorimu.

15. Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti.

16. Kenaani yìí kan náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, àwọn ará Girigaṣi,

17. àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki, àwọn ará Sini,

18. àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari, ati àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn náà ni ìran àwọn ará Kenaani tàn káàkiri.

19. Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa.

20. Àwọn ọmọ Hamu nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀, oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.

21. Ṣemu, ẹ̀gbọ́n Jafẹti, náà bí àwọn ọmọ tirẹ̀, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Eberi.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 10