Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 29:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni tí à ń báwí tí ó ń ṣoríkunkun,yóo parun lójijì láìsí àtúnṣe.

2. Nígbà tí olódodo bá di eniyan pataki,àwọn eniyan a máa yọ̀,ṣugbọn nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè,àwọn eniyan a máa kérora.

3. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn ẹni tí ń tẹ̀lé aṣẹ́wó kiri, ń fi ọrọ̀ ara rẹ̀ ṣòfò.

4. Ọba tí ó bá ń ṣe ìdájọ́ òdodo, a máa fìdí orílẹ̀-èdè múlẹ̀,ṣugbọn ọba onírìbá a máa dojú orílẹ̀-èdè bolẹ̀.

5. Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀,ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.

6. Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀.

7. Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka,ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀.

8. Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú,ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu.

9. Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́,ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín,yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́.

10. Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú,wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

11. Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.

12. Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́,gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan.

13. Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé,OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 29