Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 26:23-28 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ètè mímú ati inú burúkú,dàbí ìdàrọ́ fadaka tí a yọ́ bo ìkòkò amọ̀.

24. Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan,lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí,ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀,

25. bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́,nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.

26. Ó lè gbìyànjú láti fi ẹ̀tàn pa àrankàn rẹ̀ mọ́,ṣugbọn ìwà burúkú rẹ̀ yóo hàn ní àwùjọ gbogbo eniyan.

27. Ẹni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ni yóo já sinu rẹ̀,ẹni tí ó bá sì ń yí òkúta ni òkúta yóo pada yí lù.

28. A-purọ́-mọ́ni a máa kórìíra àwọn tí ń parọ́ mọ́,ẹni tí ń pọ́nni sì lè fa ìparun ẹni.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 26