Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 26:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ìrètí ń bẹ fún òmùgọ̀ju ẹni tí ó gbọ́n lójú ara rẹ̀ lọ.

13. Ọ̀lẹ ń wí pé, “Kinniun kan wà lọ́nà!Kinniun buburu kan wà ní ìgboro!”

14. Bí ìlẹ̀kùn ṣe ń ṣí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ìdè rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ń yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, lórí ibùsùn rẹ̀.

15. Ọ̀lẹ ti ọwọ́ bọ àwo oúnjẹ,ṣugbọn ó lẹ kọjá kí ó lè bu oúnjẹ kí ó fi bọ ẹnu.

16. Ọ̀lẹ gbọ́n lójú ara rẹ̀ju eniyan meje tí wọ́n lè dáhùn ọ̀rọ̀ pẹlu ọgbọ́n lọ.

17. Ẹni tí ó ti ọrùn bọ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀,dàbí ẹni tí ó gbá ajá alájá létí mú.

18. Bíi aṣiwèrè tí ó ju igi iná tabi ọfà olóró,

19. ni ẹni tó ṣi ẹlòmíràn lọ́nà,tí ó wá ń sọ pé “Mo kàn ń ṣeré ni!”

20. Láìsí igi, iná óo kú,bẹ́ẹ̀ ni, láìsí olófòófó, ìjà óo tán.

21. Bí èédú ti rí sí ògúnná, ati igi sí iná,bẹ́ẹ̀ ni oníjà eniyan rí, sí àtidá ìjà sílẹ̀.

22. Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ olófòófó dàbí òkèlè oúnjẹ dídùna máa wọni lára ṣinṣin.

23. Ètè mímú ati inú burúkú,dàbí ìdàrọ́ fadaka tí a yọ́ bo ìkòkò amọ̀.

24. Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan,lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí,ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀,

25. bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́,nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.

26. Ó lè gbìyànjú láti fi ẹ̀tàn pa àrankàn rẹ̀ mọ́,ṣugbọn ìwà burúkú rẹ̀ yóo hàn ní àwùjọ gbogbo eniyan.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 26