Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 22:18-28 BIBELI MIMỌ (BM)

18. nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ,tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.

19. Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ,kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé.

20. Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n,

21. láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́,kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ.

22. Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka,má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.

23. Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn,yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.

24. Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́,má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.

25. Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀,kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ.

26. Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó,má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè.

27. Tí o kò bá rí owó san fún olówó,olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ.

28. Má hú ohun tí àwọn baba ńlá rẹ rì mọ́lẹ̀,tí wọ́n fi pa ààlà kúrò.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 22