18. nítorí yóo dára tí o bá pa wọ́n mọ́ lọ́kàn rẹ,tí o sì ń fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ jáde.
19. Ìwọ ni mo sọ wọ́n di mímọ̀ fún lónìí, àní ìwọ,kí ó le jẹ́ pé OLUWA ni o gbẹ́kẹ̀lé.
20. Ṣebí mo ti kọ ọgbọ̀n àkọsílẹ̀ fún ọ lórí ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n,
21. láti fi ohun tí ó tọ̀nà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ hàn ọ́,kí o lè fi ìdáhùn pípé fún ẹni tí ó rán ọ.
22. Má ja talaka lólè, nítorí pé ó jẹ́ talaka,má sì dájọ́ èké fún ẹni tí ara ń ni.
23. Nítorí OLUWA yóo gbèjà wọn,yóo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń jẹ wọ́n níyà.
24. Má bá oníbìínú eniyan kẹ́gbẹ́,má sì bá onínúfùfù da nǹkan pọ̀.
25. Kí o má baà kọ́ ìwà rẹ̀,kí o sì fi tàkúté mú ara rẹ.
26. Má bá wọn ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tó fẹ́ yá owó,má bá wọn ṣe onídùúró fún onígbèsè.
27. Tí o kò bá rí owó san fún olówó,olówó lè pé kí wọn gba ibùsùn rẹ.