Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 21:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu.

24. “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga,tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí.

25. Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á,nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.

26. Eniyan burúkú a máa ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ìgbà,ṣugbọn olódodo ń fúnni láìdáwọ́dúró.

27. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú,pàápàá tí ó bá mú un wá pẹlu èrò ibi.

28. Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí èké yóo di asán,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹni tí ó fetí sílẹ̀ ni a óo gbàgbọ́.

29. Eniyan burúkú a máa lo ògbójú,ṣugbọn olóòótọ́ máa ń yẹ ọ̀nà ara rẹ̀ wò.

30. Kò sí ọgbọ́n, tabi òye, tabi ìmọ̀,tí ó lè dojú kọ OLUWA kí ó mókè.

31. Eniyan a máa tọ́jú ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun,ṣugbọn OLUWA ló ni ìṣẹ́gun.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 21