Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 21:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Tí a bá ṣe ìdájọ́ òtítọ́, inú olódodo a dùn,ṣugbọn ìfòyà ni fún àwọn aṣebi.

16. Ẹni tí ó sá kúrò lọ́nà òyeyóo sinmi láàrin àwọn òkú.

17. Ẹni tí ó fẹ́ràn fàájì yóo di talaka,ẹni tí ó fẹ́ràn ọtí waini ati òróró kò ní lówó lọ́wọ́.

18. Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibitíì bá dé bá olódodo.Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.

19. Ó sàn láti máa gbé ààrin aṣálẹ̀,ju kí eniyan máa bá oníjà ati oníkanra obinrin gbé lọ.

20. Ní ilé ọlọ́gbọ́n ni à á tí ń bá nǹkan olówó iyebíye,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa ba tirẹ̀ jẹ́.

21. Ẹni tí ń lépa òdodo ati àánúyóo rí ìyè, òdodo, ati iyì.

22. Ọlọ́gbọ́n a máa gba ìlú àwọn alágbáraa sì wó ibi ààbò tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé lulẹ̀.

23. Ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́pa ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu ìyọnu.

24. “Oníyẹ̀yẹ́” ni orúkọ ẹni tí ń gbéraga,tí ó sì ń ṣe mo tó báyìí-dà báyìí.

25. Ìrònú ohun tí ọ̀lẹ fẹ́ ni yóo pa á,nítorí ọwọ́ rẹ̀ kọ̀ láti ṣiṣẹ́.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 21