Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 21:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orísun omi ni ọkàn ọba lọ́wọ́ OLUWA,ibi tí ó bá wu Oluwa ni ó ń darí rẹ̀ sí.

2. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó dára lójú ara rẹ̀,ṣugbọn ọkàn ni OLUWA ń wò.

3. Kí eniyan ṣe òdodo ati ẹ̀tọ́,sàn ju ẹbọ lọ lójú OLUWA.

4. Bíi fìtílà ẹni ibi ni gbígbé ojú gangan ati ìgbéraga,ẹ̀ṣẹ̀ sì ni wọ́n.

5. Dájúdájú èrò ẹni tí ó ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn yóo yọrí sí ọ̀pọ̀,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń kánjú jù kò ní ní ànító.

6. Fífi èké kó ìṣúra jọdàbí lílé ìkùukùu, ó sì jẹ́ tàkúté ikú.

7. Ìwà ipá àwọn ẹni ibi ni yóo gbá wọn dànù,nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe òtítọ́.

8. Ọ̀nà ẹlẹ́bi kì í gún,ṣugbọn ìrìn aláìlẹ́bi a máa tọ́.

9. Ó sàn láti máa gbé kọ̀rọ̀ kan lókè àjà,ju pé kí eniyan máa bá oníjàngbọ̀n obinrin gbé ilé lọ.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 21