Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 15:6-21 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra,ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.

7. Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀,ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.

8. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA,ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.

9. OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.

10. Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.

11. Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.

12. Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.

13. Inú dídùn a máa múni dárayá,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.

14. Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.

15. Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.

16. Ó sàn kí á jẹ́ talaka, kí á sì ní ìbẹ̀rù OLUWA,ju kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí á sì kún fún ìyọnu lọ.

17. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.

18. Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.

19. Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.

20. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

21. Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 15