27. Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.
28. Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.
29. OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú,ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.
30. Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn,ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.
31. Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rereyóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.
32. Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.