Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 15:25-33 BIBELI MIMỌ (BM)

25. OLUWA a máa wó ilé agbéraga,ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.

26. Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA,ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀.

27. Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn,ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè.

28. Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú.

29. OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú,ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo.

30. Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn,ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá.

31. Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rereyóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n.

32. Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀,ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye.

33. Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n,ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 15