Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 15:17-25 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ pẹlu ìfẹ́,sàn ju ẹran mààlúù tòun ti ìkórìíra lọ.

18. Onínúfùfù a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn onínútútù a máa pẹ̀tù sí ibinu.

19. Ẹ̀gún kún bo ọ̀nà ọ̀lẹ,ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí òpópó tí ń dán.

20. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

21. Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n,ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.

22. Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú,ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere.

23. Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀,kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ!

24. Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè,kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú.

25. OLUWA a máa wó ilé agbéraga,ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 15