1. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀,ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.
2. Lẹ́nu ọlọ́gbọ́n ni ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ti ń jáde,ṣugbọn òmùgọ̀ a máa sọ̀rọ̀ agọ̀.
3. Ojú OLUWA wà níbi gbogbo,ó ń ṣọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere.
4. Ọ̀rọ̀ tí a fi pẹ̀lẹ́ sọ dàbí igi ìyè,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn a máa bani lọ́kàn jẹ́.
5. Òmùgọ̀ ọmọ á kẹ́gàn ìtọ́sọ́nà baba rẹ̀,ṣugbọn ọmọ tí ó gbọ́ ìkìlọ̀, ọlọ́gbọ́n ni.
6. Ilé olódodo kún fún ọpọlọpọ ìṣúra,ṣugbọn kìkì ìdààmú ni àkójọ èrè eniyan burúkú.
7. Ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa tan ìmọ̀ kálẹ̀,ṣugbọn ti òmùgọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.
8. Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA,ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.
9. OLUWA kórìíra ìwà àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ó fẹ́ràn àwọn tí ń hùwà òdodo.
10. Ìbáwí pupọ ń bẹ fún ẹni tí ó yapa kúrò ní ọ̀nà rere,ẹni tí ó bá kórìíra ìbáwí yóo kú.
11. Isà òkú ati ìparun kò pamọ́ lójú OLUWA,mélòó-mélòó ni ọkàn eniyan.
12. Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí,kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.
13. Inú dídùn a máa múni dárayá,ṣugbọn ìbànújẹ́ a máa mú kí ojú eniyan rẹ̀wẹ̀sì.
14. Ẹni tí ó ní òye a máa wá ìmọ̀,ṣugbọn agọ̀ ni oúnjẹ òmùgọ̀.
15. Gbogbo ọjọ́ ayé ẹni tí a ni lára kún fún ìpọ́njú,ṣugbọn ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn.