Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 1:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn òwe tí Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli pa,

2. kí àwọn eniyan lè ní ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́,kí òye ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ lè yé wọn,

3. láti gba ẹ̀kọ́, tí yóo kọ́ni lọ́gbọ́n,òdodo, ẹ̀tọ́ ati àìṣojúṣàájú,

4. láti kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́gbọ́n,kí á sì fi ìmọ̀ ati làákàyè fún ọ̀dọ́,

5. kí ọlọ́gbọ́n lè gbọ́, kí ó sì fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀,kí ẹni tí ó ní òye lè ní ìmọ̀ pẹlu.

6. Láti lè mọ òwe ati àkàwé ọ̀rọ̀,ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ati àdììtú ọ̀rọ̀.

7. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀,ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa pẹ̀gàn ọgbọ́n ati ẹ̀kọ́.

8. Ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ,má sì kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ,

9. nítorí pé ẹ̀kọ́ tí wọn bá kọ́ ọ yóo dàbí adé tí ó lẹ́wà lórí rẹ,ati bí ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.

10. Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́,o ò gbọdọ̀ gbà.

11. Bí wọn bá wí pé,“Tẹ̀lé wa ká lọ,kí á lọ sápamọ́ láti paniyan,kí á lúgọ de aláìṣẹ̀,

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 1