Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 7:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ.

2. Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ju ati lọ sí ibi àsè lọ,nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí péikú ni òpin gbogbo eniyan.Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn.

3. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn.

4. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn.

5. Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ.

6. Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu.

7. Dájúdájú, ìwà ìrẹ́jẹ a máa mú kí ọlọ́gbọ́n eniyan dàbí òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a sì máa ra eniyan níyè.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 7