Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 5:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe.

2. Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.

3. Ọpọlọpọ àkóléyà ní ń mú kí eniyan máa lá àlákálàá, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni eniyan sì fi ń mọ òmùgọ̀.

4. Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀.

5. Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ.

6. Má jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ dẹ́ṣẹ̀, kí o má baà lọ máa yí ohùn pada lọ́dọ̀ iranṣẹ Ọlọrun pé, èèṣì ló ṣe. Má jẹ́ kí Ọlọrun bínú sí ọ, kí ó má baà pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run.

7. Nígbà tí àlá bá pọ̀ ọ̀rọ̀ náà yóo pọ̀. Ṣugbọn pataki ni pé, ǹjẹ́ o tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọrun?

8. Bí o bá wà ní agbègbè tí wọ́n ti ń pọ́n talaka lójú, tí kò sì sí ìdájọ́ òdodo ati ẹ̀tọ́, má jẹ́ kí èyí yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí ẹni tí ó ga ju ọ̀gá àgbà lọ ń ṣọ́ ọ̀gá àgbà. Ẹni tó tún ga ju àwọn náà lọ tún ń ṣọ́ gbogbo wọn.

9. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba.

10. Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu.

11. Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 5