Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 4:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera,tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú.

6. Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyàju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ.

7. Mo tún rí ohun asán kan láyé:

8. Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan,kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan,sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin,bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀.Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fúntí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?”Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo.

9. Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ,nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́,èrè wọn yóo sì pọ̀.

10. Bí ọ̀kan bá ṣubú,ekeji yóo gbé e dìde.Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé!Nítorí nígbà tí ó bá ṣubúkò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde.

11. Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀,wọn yóo fi ooru mú ara wọnṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀?

12. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ,nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀.Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.

13. Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ,

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 4