Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 4:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé.Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára,Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu.Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí,kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu.

2. Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú,ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ.

3. Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá,sàn ju ti àwọn mejeeji lọ,nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibití àwọn ọmọ aráyé ń ṣe.

4. Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.

5. Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera,tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 4