Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 3:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀:

2. àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà;àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà.

3. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà,àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà.

4. Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà;àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà.

5. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà;àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà.

6. Àkókò wíwá nǹkan wà, àkókò sísọ nǹkan nù wà;àkókò fífi nǹkan pamọ́ wà, àkókò dída nǹkan nù sì wà.

7. Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà;àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà.

8. Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà;àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà.

9. Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́?

10. Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan.

11. Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.

12. Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn;

13. ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀.

14. Mo mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe, yóo wà títí lae. Kò sí ohun tí ẹ̀dá lè fi kún un, tabi tí ẹ̀dá lè yọ kúrò níbẹ̀, Ọlọrun ni ó dá a bẹ́ẹ̀ kí eniyan lè máa bẹ̀rù rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 3