Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 2:21-26 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni.

22. Kí ni eniyan rí gbà ninu gbogbo làálàá rẹ̀, kí sì ni èrè eniyan lórí akitiyan, ati iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé.

23. Nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kún fún ìrora, iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ìbànújẹ́ fún un. Ọkàn rẹ̀ kì í balẹ̀ lóru, asán ni èyí pẹlu.

24. Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá.

25. Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun.

26. Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 2