Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 10:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́,kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la,ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un.

15. Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a,tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́.

16. Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀.

17. Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ kì í bá ṣe ọmọ ẹrú ṣoríire!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá ní àsìkò tí ó tọ́;tí wọn ń jẹ tí wọn ń mu kí wọn lè lágbára,ṣugbọn tí kì í ṣe fún ìmutípara.

18. Ọ̀lẹ a máa jẹ́ kí ilé ẹni wó,ìmẹ́lẹ́ a máa jẹ́ kí ilé ẹni jò.

19. Oúnjẹ a máa múni rẹ́rìn-ín,waini a sì máa mú inú ẹni dùn,ṣugbọn owó ni ìdáhùn ohun gbogbo.

20. Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ,má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ,nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ,tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 10