Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 7:20-27 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn.

21. OLUWA ní, “N óo sọ wọ́n di ìjẹ fún àwọn àjèjì, n óo sì fi wọ́n ṣe ìkógun fún àwọn eniyan burúkú ilé ayé. Wọn óo sọ wọ́n di ohun eléèérí.

22. N óo mójú kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n lè sọ ibi dídára mi di eléèérí. Àwọn ọlọ́ṣà yóo wọnú rẹ̀, wọn yóo sì sọ ọ́ di eléèérí.

23. “Nítorí pé ìpànìyàn kún ilẹ̀ náà, ìlú wọn sì kún fún ìwà ipá.

24. N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí.

25. Nígbà tí ìrora bá dé, wọn yóo máa wá alaafia, ṣugbọn wọn kò ní rí i.

26. Àjálù yóo máa yí lu àjálù, ọ̀rọ̀ àhesọ yóo máa gorí ara wọn. Wọn yóo máa wo ojú wolii fún ìran ṣugbọn kò ní sí, alufaa kò ní náání òfin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìmọ̀ràn mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà.

27. Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 7