Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 5:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n.

13. “Bẹ́ẹ̀ ni inú mi yóo ṣe máa ru si yín, tí n óo sì bínú si yín títí n óo fi tẹ́ ara mi lọ́rùn. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo sọ̀rọ̀ pẹlu owú nígbà tí mo bá bínú si yín tẹ́rùn.

14. N óo sọ yín di ahoro ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yi yín ká ati lójú gbogbo àwọn tí wọn ń rékọjá lọ.

15. “Ẹ óo di ẹni ẹ̀sín ati ẹni ẹ̀gàn, ẹni àríkọ́gbọ́n ati ẹni àríbẹ̀rù fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká; nígbà tí mo bá fi ibinu ati ìrúnú dájọ́ fun yín, tí mo sì jẹ yín níyà pẹlu ibinu.

16. Nígbà tí mo bá ta ọfà burúkú mi si yín: ọfà ìyàn ati ọfà ìparun, tí n óo ta lù yín láti pa yín run, ìyàn óo mú lọpọlọpọ nígbà tí mo bá mú kí oúnjẹ yín tán pátá.

17. N óo rán ìyàn ati àwọn ẹranko burúkú si yín, wọn óo sì pa yín lọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ikú yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, n óo sì jẹ́ kí ogun pa yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 5