Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 48:21-29 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ilẹ̀ tí ó kù lápá ọ̀tún ati apá òsì ilẹ̀ mímọ́ náà, ati ti ìlú yóo jẹ́ ti ọba. Ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí ilẹ̀ mímọ́ pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ati ibi tí ilẹ̀ mímọ́ náà pin sí, lọ sí ààlà tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ ti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ilẹ̀ mímọ́ ati tẹmpili mímọ́ yóo sì wà láàrin rẹ̀.

22. Ilẹ̀ àwọn ọmọ Lefi ati ilẹ̀ gbogbo ìlú yóo wà láàrin ilẹ̀ ọba. Ilẹ̀ ọba yóo wà láàrin ilẹ̀ Juda ati ti Bẹnjamini.

23. Ní ti àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, Bẹnjamini yóo ní ìpín kan.

24. Ìpín ti Simeoni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Bẹnjamini, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

25. Ìpín kan tí Isakari ní yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Simeoni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

26. Ìpín kan ti Sebuluni yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Isakari, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

27. Ìpín kan ti Gadi yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Sebuluni, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

28. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè Gadi ní ìhà gúsù, ààlà ilẹ̀ náà yóo lọ láti Tamari títí dé ibi àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí dé àwọn odò Ijipti, tí ó fi lọ dé Òkun Ńlá.

29. Ilẹ̀ tí ẹ óo pín láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli nìyí; bẹ́ẹ̀ sì ni ètò bí ẹ óo ṣe pín in fún olukuluku wọn, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 48