Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 47:6-14 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ọkunrin náà bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o rí nǹkan?” Nígbà náà ni ó mú mi gba etí odò náà pada.

7. Bí mo ṣe ń pada bọ̀, mo rí ọpọlọpọ igi ní bèbè kinni keji odò náà.

8. Ó ní, “Omi yìí ń ṣàn lọ sí Araba, ní ìhà ìlà oòrùn, nígbà tí ó bá sì ṣàn wọ inú òkun, omi inú òkun, yóo di omi tí ó mọ́ gaara.

9. Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè.

10. Àwọn apẹja yóo dúró létí òkun láti Engedi títí dé Enegilaimu, ibẹ̀ yóo di ibi tí wọn yóo ti máa na àwọ̀n wọn sá sí. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóo wà níbẹ̀ bí ẹja inú Òkun Ńlá.

11. Ṣugbọn ibi ẹrọ̀fọ̀ ati àbàtà rẹ̀ kò ní di mímọ́ gaara, iyọ̀ ni yóo wà níbẹ̀.

12. Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.”

13. OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji;

14. ọgbọọgba ni ẹ sì gbọdọ̀ pín in. Mo ti búra pé n óo fún àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ìní yín.

Ka pipe ipin Isikiẹli 47