Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 47:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. OLUWA Ọlọrun ní, “Èyí ni yóo jẹ́ ààlà tí ẹ óo fi pín ilẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Josẹfu yóo ní ìpín meji;

14. ọgbọọgba ni ẹ sì gbọdọ̀ pín in. Mo ti búra pé n óo fún àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo sì di ohun ìní yín.

15. “Bí ààlà ilẹ̀ náà yóo ti lọ nìyí: ní apá àríwá, ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti Òkun Ńlá, yóo gba Etiloni títí dé ẹnubodè Hamati, títí dé ẹnu ibodè Sedadi,

16. àwọn ìlú Berota, Sibiraimu (tí ó wà ní ààlà Damasku ati Hamati), títí dé Haseri Hatikoni, tí ó wà ní ààlà Haurani.

17. Ààlà ilẹ̀ náà yóo bẹ̀rẹ̀ láti ibi òkun títí dé Hasari Enọni, tí ó wà ní ìhà àríwá ààlà Damasku, ààlà ti Hamati yóo wà ní apá àríwá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà àríwá.

18. “Ní apá ìhà ìlà oòrùn, ààlà náà yóo lọ láti Hasari Enọni tí ó wà láàrin Haurani ati Damasku, ní ẹ̀gbẹ́ odò Jọdani tí ó wà láàrin Gileadi ati ilẹ̀ Israẹli, títí dé òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì lọ títí dé Tamari. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìlà oòrùn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 47