Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 46:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹnu ọ̀nà àgbàlá inú tí ó kọjú sí ìlà oòrùn gbọdọ̀ wà ní títì fún ọjọ́ mẹfa tí a fi ń ṣiṣẹ́. Ṣugbọn ẹ máa ṣí i ní ọjọ́ ìsinmi ati ọjọ́ oṣù tuntun.

2. Yàrá àbáwọlé ẹnu ọ̀nà yìí ni ọba yóo gbà wọlé, yóo sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ẹnu ọ̀nà. Àwọn alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ti alaafia rẹ̀. Ọba yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbájáde, yóo sì jáde; ṣugbọn wọn kò ní ti ìlẹ̀kùn náà títí di ìrọ̀lẹ́.

3. Àwọn eniyan yóo jọ́sìn ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níwájú OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi ati ní ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù.

4. Ọ̀dọ́ aguntan mẹfa tí kò lábàwọ́n ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n ni ọba yóo fi rú ẹbọ ọrẹ sísun sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi.

5. Ẹbọ ọkà pẹlu àgbò yóo jẹ́ ìwọ̀n eefa kan. Ìwọ̀n ọkà pẹlu iye ọ̀dọ́ aguntan tí ó bá lágbára ni yóo fi rú ẹbọ ọkà pẹlu ọ̀dọ́ aguntan. Ṣugbọn ó gbọdọ̀ fi òróró hini kọ̀ọ̀kan ti eefa ìyẹ̀fun kọ̀ọ̀kan.

6. Ní ọjọ́ kinni oṣù, yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan mẹfa ati àgbò kan tí kò lábàwọ́n rúbọ.

7. Fún ẹbọ ohun jíjẹ, yóo tọ́jú ìwọ̀n eefa ọkà kan fún akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan, ati eefa ọkà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n ọkà tí ó bá ti lágbára fún àwọn àgbò, yóo fi hini òróró kọ̀ọ̀kan ti eefa ọkà kọ̀ọ̀kan.

8. Ẹnu ọ̀nà àbáwọlé náà ni ọba yóo gbà wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.

Ka pipe ipin Isikiẹli 46