Bí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onídàájọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí èmi gan-an yóo ti ṣe é. Wọ́n gbọdọ̀ pa àwọn òfin ati ìlànà mi mọ́ lákòókò gbogbo àṣàyàn àjọ̀dún wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́.