Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 43:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Wò ó! Ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli yọ láti apá ìlà oòrùn, ìró bíbọ̀ rẹ̀ dàbí ti omi òkun, ìmọ́lẹ̀ ògo rẹ̀ sì tàn sórí ilẹ̀.

3. Ìran tí mo rí yìí dàbí èyí tí mo rí nígbà tí Ọlọrun wá pa ìlú Jerusalẹmu run ati bí ìran tí mo rí létí odò Kebari; mo bá dojúbolẹ̀.

4. Ìtànṣán ògo OLUWA wọ inú Tẹmpili láti ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn.

5. Ẹ̀mí bá gbé mi dìde, ó mú mi wá sinu gbọ̀ngàn inú; ìtànṣán ògo OLUWA sì kún inú Tẹmpili náà.

6. Bí ọkunrin náà ti dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú Tẹmpili, ó ní:

7. “Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.

8. Wọn kò ní tẹ́ pẹpẹ wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi mọ́, tabi kí wọn gbé òpó ìlẹ̀kùn wọn sí ẹ̀gbẹ́ tèmi; tí ó fi jẹ́ pé ògiri kan ni yóo wà láàrin èmi pẹlu wọn. Wọ́n ti fi ìwà ìríra wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, nítorí náà ni mo ṣe fi ibinu pa wọ́n run.

9. Kí wọ́n pa ìwà ìbọ̀rìṣà wọn tì, kí wọ́n sì gbé òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, n óo sì máa gbé ààrin wọn títí lae.

10. “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe àpèjúwe Tẹmpili yìí, sọ bí ó ti rí ati àwòrán kíkọ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn lè tì wọ́n.

11. Bí ojú ohun tí wọ́n ṣe bá tì wọ́n, ṣe àlàyé Tẹmpili náà, bí o ti rí i, ẹnu ọ̀nà àbájáde ati àbáwọlé rẹ̀. Sọ bí o ti rí i fún wọn, sì fi àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ hàn wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀ lójú wọn, kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ ati òfin rẹ̀ mọ́.

12. Òfin Tẹmpili nìyí, gbogbo agbègbè tí ó yí orí òkè ńlá tí ó wà ká gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ jùlọ.”

13. Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan).

14. Gíga pẹpẹ láti pèpéle tí ó wà nílẹ̀ títí dé ìtẹ́lẹ̀ ìsàlẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji (mita kan). Ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan (ìdajì mita kan). Láti ìtẹ́lẹ̀ kékeré títí dé ìtẹ́lẹ̀ ńlá jẹ́ igbọnwọ mẹrin (mita meji). Ibú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan (idaji mita kan).

Ka pipe ipin Isikiẹli 43