Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 43:18-27 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ọkunrin náà wí fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Àwọn òfin pẹpẹ nìwọ̀nyí, ní ọjọ́ tí a bá gbé e kalẹ̀ láti máa rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ ati láti máa ta ẹ̀jẹ̀ sí i lára,

19. ẹ óo fún àwọn alufaa, ọmọ Lefi, láti inú ìran Sadoku, tí wọn ń rú ẹbọ sí mi, ní akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

20. Ẹ óo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ óo fi sí ara ìwo pẹpẹ ati igun mẹrẹẹrin pèpéle rẹ̀, ati ara etí rẹ̀ yíká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe wẹ pẹpẹ náà mọ́; bẹ́ẹ̀ ni ètò ìwẹ̀nùmọ́ pẹpẹ lọ.

21. Ẹ óo mú akọ mààlúù ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ẹ óo sun ún ní ibi tí a yàn lára ilẹ̀ Tẹmpili ní ìta ibi mímọ́.

22. Ní ọjọ́ keji ẹ óo fi òbúkọ tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ya pẹpẹ náà sí mímọ́ bí ẹ ti fi ẹbọ akọ mààlúù yà á sí mímọ́.

23. Bí ẹ bá ti yà á sí mímọ́ tán, ẹ óo mú akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ati àgbò tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo fi rú ẹbọ.

24. Ẹ óo kó wọn wá siwaju OLUWA, alufaa yóo wọ́n iyọ̀ lé wọn lórí, yóo sì fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA.

25. Lojoojumọ, fún ọjọ́ meje, ẹ óo máa mú ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n láti inú agbo ẹran, ẹ óo máa fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

26. Fún ọjọ́ meje ni ẹ óo fi máa rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ fún pẹpẹ náà tí ẹ óo sì máa yà á sí mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yà á sọ́tọ̀ fún lílò.

27. Tí ètò àwọn ọjọ́ wọnyi bá ti parí, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ, àwọn alufaa yóo máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí pẹpẹ náà, n óo sì máa tẹ́wọ́gbà wọ́n. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Isikiẹli 43