Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 41:7-20 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn yàrá náà ń fẹ̀ sí i láti àgbékà dé àgbékà, bí òpó tí wọ́n mọ sí ara ògiri Tẹmpili ṣe ń tóbi sí i. Àtẹ̀gùn kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Tẹmpili náà tí ó lọ sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ láti àgbékà kinni, ó gba inú ti ààrin lọ sí èyí tí ó wà lókè patapata.

8. Mo rí i pé Tẹmpili náà ní pèpéle tí ó ga yíká. Ìpìlẹ̀ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ jẹ́ ọ̀pá kan tí ó gùn ní igbọnwọ gígùn mẹfa (mita 3).

9. Ògiri ìta àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½), apá kan pèpéle tí kò ní ohunkohun lórí jẹ́ igbọnwọ marun-un. Láàrin pèpéle Tẹmpili

10. ati àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ gbọ̀ngàn fẹ̀ ní ogún igbọnwọ (mita 10), yíká gbogbo ẹ̀gbẹ́ tẹmpili.

11. Àwọn ìlẹ̀kùn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ṣí sí apá pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀. Ìlẹ̀kùn kan kọjú sí ìhà àríwá, ekeji kọjú sí ìhà gúsù. Ìbú pèpéle tí kò sí ohunkohun lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká.

12. Ilé tí ó kọjú sí àgbàlá Tẹmpili ní apá ìwọ̀ oòrùn fẹ̀ ní aadọrin igbọnwọ (mita 35), ògiri ilé náà nípọn ní igbọnwọ marun-un (mita 2½) yíká, òòró rẹ̀ sì jẹ́ aadọrun-un igbọnwọ (mita 45).

13. Lẹ́yìn náà, ó wọn Tẹmpili, ó gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45). Àgbàlá ati ilé náà pẹlu ògiri rẹ̀ gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

14. Bákan náà ni gígùn iwájú tẹmpili tí ó kọjú sí ìlà oòrùn ati àgbàlá, òun náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).

15. Lẹ́yìn náà, ó wọn òòró ilé ní ìhà tí ó dojú kọ àgbàlá tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn ati àwọn ògiri rẹ̀; ẹ̀gbẹ́ kinni keji gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45).Pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni wọ́n fi bo ara ògiri ibi mímọ́ jùlọ Tẹmpili náà ati yàrá inú ati

16. ìloro ti ìta yíká. Àwọn mẹtẹẹta ní fèrèsé aláṣìítì. Wọ́n fi pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo ara ògiri Tẹmpili náà yíká láti ilẹ̀ títí kan ibi fèrèsé, títí kọjá ìloro. (Wọ́n fi pákó bo àwọn fèrèsé náà).

17. Ati ààyè tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà, títí kan yàrá inú pàápàá, ati ẹ̀yìn ìta. Gbogbo ara ògiri yàrá inú yíká ati ibi mímọ́ ni wọ́n gbẹ́

18. àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí yíká; wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ kọ̀ọ̀kan sí ààrin kerubu meji meji.

19. Kerubu kọ̀ọ̀kan ní iwájú meji meji. Iwájú tí ó dàbí ti eniyan kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ekeji tí ó dàbí ti ọ̀dọ́ kinniun kọjú sí igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ keji. Wọ́n gbẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ sí ara Tẹmpili yíká.

20. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ ati kerubu sí ara ògiri náà láti ilẹ̀ títí dé òkè ìlẹ̀kùn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 41