Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 40:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Mo rí ògiri kan tí ó yí ibi tí tẹmpili wà ká. Ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọkunrin tí mo kọ́ rí gùn ní igbọnwọ mẹfa. Igbọnwọ kọ̀ọ̀kan ọ̀pá tirẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, (ìdajì mita kan). Ó sì wọn ògiri náà. Ó fẹ̀ ní ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ kan, ó sì ga ní ọ̀pá kan, (mita 3).

6. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ó gun àtẹ̀gùn tí ó wà níbẹ̀, ó sì wọn àbáwọlé ẹnu ọ̀nà náà; ó jìn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, (mita 3).

7. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà gùn ní ìwọ̀n ọ̀pá kan, wọ́n sì fẹ̀ ní ìwọ̀n ọ̀pá kan. Àlàfo tí ó wà láàrin àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2½). Àbáwọlé ẹnu ọ̀nà ẹ̀bá ìloro tí ó kọjú sí tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan.

8. Lẹ́yìn náà ó wọn ìloro ẹnu ọ̀nà tí ó wà ninu, ó jẹ́ igbọnwọ mẹjọ (mita 4),

9. àtẹ́rígbà rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, mita kan. Ìloro ẹnu ọ̀nà náà wà ninu patapata.

10. Yàrá mẹta mẹta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnu ọ̀nà náà. Bákan náà ni ìwọ̀n àwọn yàrá mẹtẹẹta rí. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwọ̀n àtẹ́rígbà wọn, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji.

11. Lẹ́yìn náà, ó wọn ìbú àbáwọlé ẹnu ọ̀nà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5). Ó wọn gígùn ẹnu ọ̀nà náà, ó jẹ́ igbọnwọ mẹtala (mita 6½).

12. Ògiri kan wà níwájú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà, ó ga ní igbọnwọ kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji. Ati òòró ati ìbú àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ náà jẹ́ igbọnwọ mẹfa mẹfa (mita 3).

13. Ó wọn ẹnu ọ̀nà náà láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ kan títí dé ẹ̀yìn yàrá ẹ̀gbẹ́ keji, ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), láti ìlẹ̀kùn kinni sí ekeji.

14. Ó tún wọn ìloro, ó jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Gbọ̀ngàn kan yí ìloro ẹnu ọ̀nà ká

Ka pipe ipin Isikiẹli 40