Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 40:30-48 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Àwọn ìloro wà yí i ká, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½), wọ́n sì fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un (mita 2½).

31. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

32. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìhà ìlà oòrùn gbọ̀ngàn inú, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, bákan náà ni ó rí pẹlu àwọn yòókù.

33. Bákan náà sì ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ati àtẹ́rígbà, ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, fèrèsé wà lára òun náà yíká ninu, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìloro rẹ̀. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

34. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

35. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ibi ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá, ó sì wọ̀n ọ́n, bákan náà ni òun náà rí pẹlu àwọn yòókù.

36. Bákan náà ni àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtẹ́rígbà rẹ̀ ati ìloro rẹ̀ rí pẹlu àwọn yòókù, ó sì ní fèrèsé yíká. Òòró rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹẹdọgbọn (mita 12½).

37. Ìloro rẹ̀ kọjú sí gbọ̀ngàn òde, àwòrán ọ̀pẹ wà lára àtẹ́rígbà rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji, àtẹ̀gùn rẹ̀ sì ní ìgbésẹ̀ mẹjọ.

38. Yàrá kan wà tí ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ninu ìloro ẹnu ọ̀nà, níbẹ̀ ni wọ́n tí ń fọ ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun.

39. Tabili meji meji wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà, lórí wọn ni wọ́n tí ń pa àwọn ẹran ẹbọ sísun, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

40. Tabili meji wà ní ìta ìloro náà, ní ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá, tabili meji sì tún wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ìloro ẹnu ọ̀nà náà.

41. Tabili mẹrin wà ninu, mẹrin sì wà ní ìta, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà; gbogbo rẹ̀ jẹ́ tabili mẹjọ. Lórí wọn ni wọ́n tí ń pa ẹran ìrúbọ.

42. Tabili mẹrin kan tún wà tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Òòró rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ìbú rẹ̀ náà jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀ (mita 7), ó sì ga ní igbọnwọ kan (bíi ìdajì mita). Lórí rẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa ẹran ẹbọ sísun ati ti ẹbọ yòókù sí.

43. Wọ́n kan àwọn ìkọ́ kan tí ó gùn ní ìwọ̀n àtẹ́lẹwọ́ kan mọ́ ara tabili yíká ninu. Wọn a máa gbé ẹran tí wọn yóo bá fi rúbọ lé orí àwọn tabili náà.

44. Lẹ́yìn náà ó mú mi wọ gbọ̀ngàn ti inú. Mo rí yàrá meji ninu gbọ̀ngàn yìí: ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá, ó dojú kọ ìhà gúsù, ekeji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìhà gúsù, ó dojú kọ ìhà àríwá.

45. Ó wí fún mi pé àwọn alufaa tí ń mójútó tẹmpili ni wọ́n ni yàrá tí ó kọjú sí ìhà gúsù.

46. Yàrá tí ó kọjú sí ìhà àríwá jẹ́ ti àwọn alufaa tí wọn ń mójútó pẹpẹ; àwọn ni àwọn ọmọ Sadoku. Àwọn nìkan ninu ìran Lefi ni wọ́n lè súnmọ́ OLUWA láti rúbọ sí i.

47. Ó wọn gbọ̀ngàn ti inú, òòró rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 45), igun rẹ̀ mẹrẹẹrin dọ́gba, pẹpẹ sì wà níwájú tẹmpili.

48. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ìloro tẹmpili, ó sì wọn àtẹ́rígbà rẹ̀. Ó jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un (mita 2½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji; ìbú ẹnu ọ̀nà náà jẹ́ igbọnwọ mẹrinla (mita 7). Àwọn ògiri rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta mẹta (mita 1½), ní ẹ̀gbẹ́ kinni ati ikeji.

Ka pipe ipin Isikiẹli 40