Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 37:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè.

6. N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

7. Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Bí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ariwo ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí so mọ́ ara wọn; egungun ń so mọ́ egungun.

8. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, iṣan ti dé ara wọn, ẹran ti bo iṣan, awọ ara sì ti bò wọ́n, ṣugbọn kò tíì sí èémí ninu wọn.

9. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún èémí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Wá, ìwọ èémí láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé, kí o fẹ́ sinu àwọn òkú wọnyi, kí wọ́n di alààyè.’ ”

10. Mo bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí ó ti pàṣẹ fún mi. Èémí wọ inú wọn, wọ́n sì di alààyè; ogunlọ́gọ̀ eniyan ni wọ́n, wọ́n bá dìde dúró!

11. OLUWA bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọ Israẹli ni àwọn egungun wọnyi. Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ; kò sí ìrètí fún wa mọ́, a ti pa wá run patapata.’

12. Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli.

13. Ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ṣí ibojì yín, tí mo sì gbe yín dìde, ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

14. N óo fi ẹ̀mí mi sinu yín, ẹ óo sì tún wà láàyè; n óo sì mu yín wá sí ilẹ̀ yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀, tí mo sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Isikiẹli 37