Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 34:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣé àjẹkù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀ ni ó yẹ kí àwọn aguntan tèmi máa jẹ; omi àmukù tí ẹ ti fi ẹsẹ̀ dàrú sì ni ó yẹ kí wọn máa mu?

20. “Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun, ń sọ fun yín ni pé: mo ṣetán tí n óo ṣe ìdájọ́ fún àwọn aguntan tí ó sanra ati àwọn aguntan tí kò lókun ninu.

21. Nítorí pé ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ ti àwọn tí wọn kò lágbára sọnù, ẹ sì ń kàn wọ́n níwo títí tí ẹ fi tú wọn ká.

22. N óo gba àwọn aguntan mi sílẹ̀, wọn kò ní jẹ́ ìjẹ mọ́, n óo sì ṣe ìdájọ́ láàrin aguntan kan ati aguntan keji.

23. Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn.

24. Èmi OLUWA ni n óo jẹ́ Ọlọrun wọn; Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo sì jẹ́ ọba láàrin wọn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

25. N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu.

26. “N óo bukun àwọn, ati gbogbo agbègbè òkè mi. N óo máa jẹ́ kí òjò máa rọ̀ lásìkò wọn, òjò ibukun ni yóo sì máa jẹ́.

27. Igi inú oko yóo máa so; ilẹ̀ yóo sì máa mú ọpọlọpọ irúgbìn jáde. Àwọn eniyan óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà wọn, tí mo bá sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú.

28. Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.

29. N óo fún wọn ní ọpọlọpọ nǹkan kórè ninu ohun tí wọ́n bá gbìn, ìyàn kò ní run wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ náà, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kò sì ní fi wọ́n ṣẹ̀sín mọ́.

30. Wọn óo mọ̀ pé èmi, OLUWA Ọlọrun wọn, wà pẹlu wọn, ati pé àwọn ọmọ Israẹli sì ni eniyan mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31. “Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 34