Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 32:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé.

10. N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.”

11. OLUWA Ọlọrun sọ fún ọba Ijipti pé, “Ọba Babiloni yóo fi idà pa yín.

12. N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun.

13. N óo pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Ijipti tí ó wà ní etí odò run. Àwọn eniyan kò sì ní fi ẹsẹ̀ da omi rú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko kò ní fi pátákò da odò rú mọ́.

14. N óo wá jẹ́ kí odò wọn ó tòrò, kí wọn máa ṣàn bí òróró. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15. Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro, tí mo bá pa gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ run; tí mo bá pa gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ run, wọn yóo mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

16. Àwọn eniyan yóo máa kọ ọ̀rọ̀ yìí ní orin arò; àwọn ọmọbinrin ní àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa kọ ọ́. Wọn óo máa kọ ọ́ nípa Ijipti ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Èmi, OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

17. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ọdún kejila tí a ti wà ní ìgbèkùn,

18. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan Ijipti, rán àwọn ati àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá yòókù lọ sinu isà òkú, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ilẹ̀ bora.

19. Sọ fún wọn pé,‘Ta ni ó lẹ́wà jùlọ?Sùn kalẹ̀, kí á sì tẹ́ ọ sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.’

20. “Wọn yóo ṣubú láàrin àwọn tí wọ́n kú ikú ogun; ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ yóo ṣubú pẹlu rẹ̀.

21. Àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ akọni ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn yóo máa sọ nípa wọn ninu isà òkú pé, ‘Àwọn aláìkọlà tí a fi idà pa ti ṣubú, wọ́n ti wọlẹ̀, wọ́n sùn, wọn kò lè mira.’

22. “Asiria náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ibojì àwọn tí wọ́n ti kú yí i ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.

Ka pipe ipin Isikiẹli 32