Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 32:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbé ohùn sókè kí o kọ orin arò nípa Farao, ọba Ijipti. Wí fún un pé ó ka ara rẹ̀ kún kinniun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ó dàbí diragoni ninu omi. Ó ń jáde tagbára tagbára láti inú odò, ó ń fẹsẹ̀ da omi rú, ó sì ń dọ̀tí àwọn odò.

3. Sọ pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní n óo da àwọ̀n mi bò ó níṣojú ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan; wọn óo sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ sókè.

4. N óo wọ́ ọ jù sórí ilẹ̀; inú pápá ni n óo sọ ọ́ sí, n óo jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run pa ìtẹ́ wọn lé e lórí. N óo sì jẹ́ kí àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé jẹ ẹran ara rẹ.

5. N óo sọ ẹran ara rẹ̀ káàkiri sí orí àwọn òkè. N óo sì fi òkú rẹ̀ kún àwọn àfonífojì.

6. N óo tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà sórí ilẹ̀ ati sórí àwọn òkè, gbogbo ipadò yóo sì kún fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

7. Nígbà tí mo bá pa á rẹ́, n óo bo ojú ọ̀run; n óo jẹ́ kí ìràwọ̀ ṣóòkùn n óo fi ìkùukùu bo oòrùn lójú, òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.

8. Gbogbo àwọn ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tàn lójú ọ̀run ni n óo jẹ́ kí ó di òkùnkùn lórí rẹ̀, n óo jẹ́ kí òkùnkùn bo ilẹ̀ rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. “N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé.

10. N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.”

11. OLUWA Ọlọrun sọ fún ọba Ijipti pé, “Ọba Babiloni yóo fi idà pa yín.

12. N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun.

13. N óo pa gbogbo ẹran ọ̀sìn Ijipti tí ó wà ní etí odò run. Àwọn eniyan kò sì ní fi ẹsẹ̀ da omi rú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko kò ní fi pátákò da odò rú mọ́.

14. N óo wá jẹ́ kí odò wọn ó tòrò, kí wọn máa ṣàn bí òróró. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 32