Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 3:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mo bá dé Teli Abibu lọ́dọ̀ àwọn ìgbèkùn tí wọn ń gbé ẹ̀bá odò Kebari. Ọjọ́ meje ni mo fi wà pẹlu wọn, tí mo jókòó tì wọ́n, tí mò ń wò wọ́n tìyanu-tìyanu.

16. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

17. “Ọmọ eniyan, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli. Nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ohunkohun lẹ́nu mi, o gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn.

18. Bí mo bá sọ fún eniyan burúkú pé dájúdájú yóo kú, ṣugbọn tí o kò kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi tí ó ń rìn kí ó lè yè, eniyan burúkú náà yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣugbọn lọ́wọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

19. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú, tí kò bá yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú tí ó ń ṣe, tabi ọ̀nà ibi tí ó ń tọ̀; yóo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ óo gba ara rẹ là.

20. “Bẹ́ẹ̀ náà sì ni bí olódodo bá yipada kúrò ninu òdodo rẹ̀, tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, tí mo sì gbé ohun ìkọsẹ̀ kan siwaju rẹ̀, yóo kú, nítorí pé o kò kìlọ̀ fún un, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò sì ní ranti iṣẹ́ òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe; ṣugbọn n óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.

21. Ṣugbọn bí o bá kìlọ̀ fún olódodo náà pé kí ó má dẹ́ṣẹ̀, tí kò sì dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú yóo yè, nítorí pé ó gbọ́ ìkìlọ̀; ìwọ náà yóo sì gba ẹ̀mí ara rẹ là.”

22. Ẹ̀mí OLUWA sì wà lára mi, ó sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí àfonífojì, níbẹ̀ ni n óo ti bá ọ sọ̀rọ̀.”

23. Mo bá dìde, mo jáde lọ sí àfonífojì. Mo rí ìfarahàn ògo OLUWA níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti rí i lẹ́bàá odò Kebari, mo bá dojúbolẹ̀.

24. Ṣugbọn ẹ̀mí Ọlọrun kó sí mi ninu, ó sì gbé mi nàró; ó bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, “Lọ ti ara rẹ mọ́ ilé rẹ.

25. Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! A óo na okùn lé ọ lórí, a óo sì fi okùn náà dè ọ́, kí o má baà lè jáde sí ààrin àwọn eniyan.

26. N óo mú kí ahọ́n rẹ lẹ̀ mọ́ ọ lẹ́nu kí o sì ya odi, kí o má baà lè kìlọ̀ fún wọn, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.

27. Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 3