Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 27:25-36 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Àwọn ọkọ̀ Taṣiṣi ní ń bá ọ ru ọjà rẹ lọ ta.Ọjà kún inú rẹ,ẹrù rìn ọ́ mọ́lẹ̀ láàrin omi òkun.

26. Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun.Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun.

27. Gbogbo ọrọ̀ rẹ, ati gbogbo ọjà olówó iyebíye rẹ,àwọn tí ń tu ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń darí rẹ;àwọn tí ń fi ọ̀dà dí ihò ara ọkọ̀ rẹati àwọn tí ń bá ọ ṣòwò.Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ ati àwọn èrò tí ó wà ninu rẹ,ni yóo rì sí ààrin gbùngbùn òkun, ní ọjọ́ ìparun rẹ.

28. Gbogbo èbúté yóo mì tìtìnígbà tí àwọn tí wọn ń tọ́ ọkọ̀ rẹ bá kígbe.

29. Gbogbo àwọn atukọ̀ ni yóo jáde kúrò ninu ọkọ̀.Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ọkọ̀ati àwọn tí ń darí ọkọ̀yóo dúró ní èbúté.

30. Wọn óo gbé ohùn sókè sí ọ,wọn óo sun ẹkún kíkan kíkan.Wọn óo da erùpẹ̀ sórí wọn,wọn óo yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú.

31. Wọn óo fá irun orí wọn nítorí rẹ,wọn óo sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìdí,wọn óo sì fi ìbànújẹ́ ọkàn sọkún nítorí rẹ,inú wọn yóo sì bàjẹ́.

32. Bí wọ́n bá ti ń sọkún,wọn óo máa kọ orin arò nípa rẹ báyìí pé:‘Ìlú wo ló tíì parun bíi Tire, láàrin òkun?

33. Nígbà tí àwọn ọjà rẹ bá dé láti òkè òkun,ò ń tẹ́ ọpọlọpọ eniyan lọ́rùn.Ò ń fi ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹsọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34. Wàyí ò, omi òkun ti fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́,o ti rì sí ìsàlẹ̀ òkun.’Gbogbo àwọn ọjà rẹati àwọn tí ń wa ọkọ̀ rẹ ti rì pẹlu rẹ.

35. “Ẹnu ya gbogbo àwọn tí ń gbé etí òkun nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àwọn ọba wọn ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹ̀rù sì hàn ní ojú wọn.

36. Àwọn oníṣòwò orílẹ̀-èdè ayé ń pòṣé lé ọ lórí. Òpin burúkú dé bá ọ, o kò ní sí mọ́ títí lae.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 27