Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 27:10-23 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Àwọn ará Pasia ati àwọn ará Ludi ati àwọn ará Puti wà láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ bí akọni. Wọ́n gbé asà ati àṣíborí wọn kọ́ sinu rẹ, wọ́n jẹ́ kí o gba ògo.

11. Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé.

12. “Àwọn ará Taṣiṣi ń bá ọ rajà nítorí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ: fadaka, irin, páànù ati òjé ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.

13. Àwọn ará Jafani, Tubali, ati Meṣeki ń bá ọ ṣòwò; wọ́n ń kó ẹrú ati ohun èlò idẹ wá fún ọ, wọn fi ń gba àwọn nǹkan tí ò ń tà.

14. Àwọn ará Beti Togama a máa kó ẹṣin, ati ẹṣin ogun, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

15. Àwọn ará Didani ń bá ọ ṣòwò, ọpọlọpọ etíkun ni ẹ tí ń tajà, wọ́n ń fi eyín erin ati igi Ẹboni ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

16. Àwọn ará Edomu bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà tí ò ń tà. Òkúta emeradi, aṣọ àlàárì, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́, iyùn ati òkúta agate ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọ.

17. Juda ati ilé Israẹli bá ọ ṣòwò: wọ́n ń kó ọkà, èso olifi, àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, oyin, òróró ati òrí wá láti fi ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan tí ò ń tà.

18. Àwọn ará Damasku bá ọ ṣòwò nítorí ọpọlọpọ ọjà ati àwọn nǹkan olówó iyebíye tí ò ń tà, wọ́n mú ọtí waini ati irun aguntan funfun wá láti Heliboni.

19. Àwọn ará Fedani ati Jafani láti Usali a máa wá fi ọtí waini pààrọ̀ ohun tí ò ń tà; wọn a kó àwọn nǹkan èlò irin wá, ati igi kasia.

20. Àwọn ará Dedani náà ń bá ọ ṣòwò, wọ́n ń kó aṣọ gàárì tí wọ́n fi ń gun ẹṣin wá.

21. Àwọn ará Arabia ati àwọn olóyè Kedari ni àwọn oníbàárà rẹ pataki, wọn a máa ra ọ̀dọ́ aguntan, àgbò, ati ewúrẹ́ lọ́wọ́ rẹ.

22. Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ.

23. Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò.

Ka pipe ipin Isikiẹli 27