Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 27:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọ orin arò nípa ìlú Tire.

3. Sọ fún ìlú Tire tí ó wà ní etí òkun, tí ń bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ṣòwò. Sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní:Tire, ìwọ tí ò ń sọ pé,o dára tóbẹ́ẹ̀, tí ẹwà rẹ kò kù síbìkan!

4. Agbami òkun ni bodè rẹ.Àwọn tí wọ́n kọ́ ọ fi ẹwà jíǹkí rẹ.

5. Igi firi láti Seniri ni wọ́n fi ṣe gbogbo ẹ̀gbẹ́ rẹ.Igi kedari láti Lẹbanoni ni wọ́n sì fi ṣe òpó ọkọ̀ rẹ.

6. Igi oaku láti Baṣani ni wọ́n fi ṣe ajẹ̀ rẹ̀Igi sipirẹsi láti erékùṣù Kipru ni wọ́n fi ṣe ilé rẹ.Wọ́n sì fi eyín erin bo inú rẹ̀.

7. Aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára láti ilẹ̀ Ijipti,ni wọ́n fi ṣe ìgbòkun rẹtí ó dàbí àsíá ọkọ̀ rẹ.Aṣọ aláró ati aṣọ àlàárì láti etíkun Eliṣani wọ́n fi ṣe ìbòrí rẹ.

8. Àwọn ará Sidoni ati Arifadi ni atukọ̀ rẹ.Àwọn ọlọ́gbọ́n láti ilẹ̀ Ṣemeri wà lọ́dọ̀ rẹ,àwọn ni wọ́n ń darí ọkọ̀ ojú omi rẹ.

9. Àwọn àgbààgbà Gebali ati àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n oníṣẹ́ ọwọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ,àwọn ni wọ́n ń fi ọ̀dà dí ọkọ̀ rẹkí omi má baà wọnú rẹ̀.Gbogbo ọkọ̀ ojú omi ati àwọn tí ń tù wọ́nwà lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n ń bá ọ ra ọjà.

10. “Àwọn ará Pasia ati àwọn ará Ludi ati àwọn ará Puti wà láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ bí akọni. Wọ́n gbé asà ati àṣíborí wọn kọ́ sinu rẹ, wọ́n jẹ́ kí o gba ògo.

11. Àwọn ará Arifadi ati Heleki wà lórí odi rẹ yíká, àwọn ará Gamadi sì wà ninu àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ. Wọ́n gbé asà wọn kọ́ káàkiri ara ògiri rẹ, àwọn ni wọ́n mú kí ẹwà rẹ pé.

12. “Àwọn ará Taṣiṣi ń bá ọ rajà nítorí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ: fadaka, irin, páànù ati òjé ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.

Ka pipe ipin Isikiẹli 27