Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 24:12-27 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Lásán ni mò ń ṣe wahala, gbogbo ìpẹtà náà kò ní jóná.

13. Jerusalẹmu, ìṣekúṣe ti dípẹtà sinu rẹ, mo fọ̀ ọ́ títí, ìdọ̀tí kò kúrò ninu rẹ, kò sì ní kúrò mọ́ títí n óo fi bínú sí ọ tẹ́rùn.

14. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Bí mo ti wí ni n óo ṣe, n kò ní dáwọ́ dúró, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yí ọkàn pada. Ìwà ati ìṣe yín ni n óo fi da yín lẹ́jọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16. “Ìwọ ọmọ eniyan, wò ó! Mo ṣetán tí n óo gba ohun tí ń dùn ọ́ ninu lọ́wọ́ rẹ. Lójijì ni n óo gbà á, o kò sì gbọdọ̀ banújẹ́ tabi kí o sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omi kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀ lójú rẹ.

17. O lè mí ìmí ẹ̀dùn, ṣugbọn a kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn rẹ, o kò sì gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀. Wé lawani mọ́rí, sì wọ bàtà. O kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu, o kò sì gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.”

18. Mo bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ láàárọ̀, nígbà tí ó di àṣáálẹ́, iyawo mi kú. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ pé kí n ṣe.

19. Àwọn eniyan bá bi mí pé, “Ṣé kò yẹ kí o sọ ohun tí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa, tí o fi ń ṣe báyìí.”

20. Mo bá sọ fún wọn pé, “OLUWA ni ó bá mi sọ̀rọ̀,

21. tí ó ní kí n sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé òun OLUWA sọ pé òun óo sọ ibi mímọ́ òun di aláìmọ́: ibi mímọ́ òun tí ẹ fi ń ṣògo, tí ó jẹ́ agbára yín, tí ẹ fẹ́ràn láti máa wò, tí ọkàn yín sì fẹ́. Ogun yóo pa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín tí ẹ fi sílẹ̀.

22. Bí mo ti ṣe yìí gan-an ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe, ẹ kò gbọdọ̀ fi aṣọ bo ẹnu yín tabi kí ẹ máa jẹ oúnjẹ ọlọ́fọ̀.

23. Lawani yín gbọdọ̀ wà lórí yín; kí bàtà yín sì wà ní ẹsẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣọ̀fọ̀ tabi kí ẹ sọkún. Ẹ óo joró nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tẹ̀dùntẹ̀dùn.

24. Ó ní èmi Isikiẹli óo jẹ́ àmì fun yín, gbogbo bí mo bá ti ṣe ni ẹ̀yin náà gbọdọ̀ ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹlẹ̀. Ẹ óo sì mọ̀ pé òun ni OLUWA Ọlọrun.”

25. OLUWA ní, “Ìwọ ní tìrẹ, ọmọ eniyan, ní ọjọ́ tí mo bá gba ibi ààbò wọn lọ́wọ́ wọn, àní ayọ̀ ati ògo wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ máa rí, tí ọkàn wọn sì fẹ́, pẹlu àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin,

26. ní ọjọ́ náà, ẹnìkan tí yóo sá àsálà ni yóo wá fún ọ ní ìròyìn.

27. Ní ọjọ́ náà, ẹnu rẹ óo yà, o óo sì le sọ̀rọ̀; o kò ní ya odi mọ́. Ìwọ ni o óo jẹ́ àmì fún wọn; wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 24