Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 24:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ kẹwaa, oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an tí a ti wà ní ìgbèkùn, ó ní,

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, sàmì sí ọjọ́ òní, kọ orúkọ ọjọ́ òní sílẹ̀. Lónìí gan-an ni ọba Babilonia gbógun ti Jerusalẹmu.

3. Pa òwe yìí fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kí o sì wí fún wọn pé, ní orúkọ èmi OLUWA Ọlọrun: Gbé ìkòkò kaná;bu omi sí i.

4. Kó ègé ẹran sí i,gbogbo ibi tí ó dára jùlọ lára ẹran,ẹran itan ati ti èjìká,kó egungun tí ó dára náà sí i kí ó kún.

5. Ẹran tí ó dára jùlọ ninu agbo ni kí o mú,kó igi jọ sí abẹ́ ìkòkò náà,kí o bọ ẹran náà,bọ̀ ọ́ teegunteegun.”

6. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú apànìyàn, ìkòkò tí inú rẹ̀ dípẹtà, tí ìdọ̀tí rẹ̀ kò ṣí kúrò ninu rẹ̀! Yọ ẹran inú rẹ̀ kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, sá máa mú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti bà.

7. Nítorí pé ẹ̀jẹ̀ eniyan tí ó pa wà ninu rẹ̀, orí àpáta ni ó da ẹ̀jẹ̀ wọn sí, kò dà á sórí ilẹ̀, tí yóo fi rí erùpẹ̀ bò ó.

8. Mo ti da ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ sórí àpáta, kí ó má baà ṣe é bò mọ́lẹ̀. Kí inú lè bí mi, kí n lè gbẹ̀san.”

9. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ègbé ni fún ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí, èmi fúnra mi ni n óo kó iná ńlá jọ.

Ka pipe ipin Isikiẹli 24