Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 23:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọmọbinrin meji kan wà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà.

3. Wọ́n lọ ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Ijipti nígbà tí wọ́n jẹ́ ọmọge. Àwọn kan fọwọ́ fún wọn lọ́mú, wọ́n fọwọ́ pa orí ọmú wọn nígbà tí wọn kò tíì mọ ọkunrin.

4. Orúkọ ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Ohola, ti àbúrò sì ń jẹ́ Oholiba. Àwọn mejeeji di tèmi; wọ́n sì bímọ lọkunrin ati lobinrin. Èyí tí ń jẹ́ Ohola ni Samaria, èyí tí ń jẹ́ Oholiba ni Jerusalẹmu.

5. Ohola tún lọ ṣe àgbèrè lẹ́yìn tí ó ti di tèmi, ó tún ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria, olólùfẹ́ rẹ̀:

6. àwọn ọmọ ogun tí wọn ń wọ aṣọ àlàárì, àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn sì fanimọ́ra.

7. Ó bá gbogbo àwọn eniyan pataki pataki Asiria ṣe àgbèrè, ó sì fi oriṣa gbogbo àwọn tí ó ń ṣẹ́jú sí ba ara rẹ̀ jẹ́.

8. Kò kọ ìwà àgbèrè rẹ̀ tí ó ń hù nígbà tí ó ti wà ní ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀. Nígbà èwe rẹ̀, àwọn ọkunrin bá a lòpọ̀, wọ́n fọwọ́ pa á lọ́mú, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀.

9. Nítorí gbogbo èyí, mo fi lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, àwọn ará Asiria tí ó ń ṣẹ́jú sí.

10. Wọ́n tú aṣọ lára rẹ̀, wọ́n kó àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin; wọ́n sì fi idà pa òun alára. Orúkọ rẹ̀ wá di yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn obinrin nígbà tí ìdájọ́ dé bá a.

11. “Oholiba, àbúrò rẹ̀ rí èyí, sibẹsibẹ, ojú ṣíṣẹ́ sí ọkunrin ati àgbèrè tirẹ̀ burú ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ.

12. Ó ń ṣẹ́jú sí àwọn ará Asiria: àwọn gomina ati àwọn ọ̀gágun, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ihamọra, tí wọn ń gun ẹṣin, ọdọmọkunrin ni gbogbo wọn, ojú wọn fanimọ́ra.

Ka pipe ipin Isikiẹli 23