Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 2:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, dìde dúró, mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”

2. Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí OLUWA wọ inú mi, ó gbé mi nàró, mo sì gbọ́ bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀.

3. Ó ní, “Ọmọ eniyan, mo rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, orílẹ̀-èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Àwọn ati àwọn baba ńlá wọn ṣì tún ń bá mi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.

4. Aláfojúdi ati olóríkunkun ẹ̀dá ni wọ́n. Mò ń rán ọ sí wọn kí o lè sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun wí fún wọn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 2