Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 16:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́; mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn.

12. Mo fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tí ó lẹ́wà dé ọ lórí.

13. Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin.

14. Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15. “Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè.

16. O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.

17. O mú ninu àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka rẹ, tí mo fún ọ, o fi wọ́n ṣe ère ọkunrin, o sì ń bá wọn ṣe àgbèrè.

18. O mú aṣọ rẹ tí a ṣe ọnà sí lára, o dà á bò wọ́n. O gbé òróró ati turari mi kalẹ̀ níwájú wọn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 16